EWI (POEM) RENDITION BY PASTOR E.A ADEBOYE DURING THE 69TH RCCG ANNUAL CONVENTION 2021 (VIDEO LINK INCLUDED)

EWI (POEM) RENDITION BY PASTOR E.A ADEBOYE DURING THE 69TH RCCG ANNUAL CONVENTION 2021

Jesu ye ni gba gbogbo
Jesu mi wa laaye
Jesu ye lat’oni lo o
Jesu mi wa laaye
Jesu ye ni gba ku gba
Jesu mi wa laaye
Jesu ye lat’oni lo o
Jesu mi wa laaye

O n gbala ni gba gbogbo
Jesu mi wa laaye
Jesu ye lat’oni lo o
Jesu mi wa laaye
O ngbala ni gba ku gba
Jesu mi wa laaye
Jesu ye lat’oni lo o

O nlani ni gba ku gba
Jesu mi wa laaye
Jesu ye lat’oni lo o

O nwosan ni gba gbogbo
Jesu mi wa laaye
Jesu ye lat’oni lo o

O nwosan ni gba ku gba
Jesu mi wa laaye
Jesu ye lat’oni lo o

O n pese ni gba gbogbo
Jesu mi wa laaye
O wa lat’oni lo o
Jesu mi wa laaye

Hallelujah, hallelujah
Jesu mi wa laaye
Hallelujah hallelujah o
Jesu mi wa laaye

Asa wa n titi wa n titi
Awodi wa nkoro wa nkoro
Baba nla asa, kole fi ahun s’oje
Awodi oke, kole f’ahun s’okele gbemi
Opolo nyan kanjukanju niwaju elegusi
Elegusi kole fi opolo s’ohunkohun
Iwa wo aparo bi kafidala ni
iwa wo aparo bi kodiro ikoko obe
Sugbon ori eye kopa eye, eleda aparo koje kod’iro obe
Kowokowo araba owo mo, ojuti iroko, opekete n dagba, ina adamo nbaje, a ndi baba lo, inu nbi abinu eni, igi ti won rope oma subu, iise lo duro reterete, ara san, ategu nfe, iji ja, koma gba wa lo o, oye kadupe abi oye? Opo ojo lo ran, opo ojo lo s’agbara, gbogbo re nile fi mu, ogo fun Olorun loke orun, sebi ola abata ohun lo m’odo san, ola baba ohun lo m’omo yan, bikobasi t’olugbala ni, aye iba yowa gbogbo ayo wa, ebati d’opin patako, opelope ejika Jesu tikoje kii orun wa o wo, opelope Oluwa ohun onije k’ota oyo wa, laise iranlowo Olorun ni, aye ibayosuti siwa, opelope anu Olodumare, oba gbogbo ninu ohun gbogbo, ala inu ina koja koje ki ina ojo wa run, arin larin odo, odo kobowa mole, bi esu ti rope oma ri, bee ko lo ri, gbogbo imoran ota gbogbo e ni Olorun san di ofo, gbogbo iyin omo Olorun, eyin omo Igbala, ebami ke hallelujah soke,


Oro dori kod’ori, odori isele nla ko, tose lojojosi, tose lojojohun, ni ibere itan, okorin kan wa, olowo, olola, ob’imo gidi, okurin meji, obirin meta, obajumo, ol’okiki nigba aye tire, kosi igbakeji re, eniyan otan ni, osi wa feran Oluwa, oberu Edumare de bi pe Olorun paapa jireri wipe oferan ohun, okorera ibi, sibesibe, isile nla ko se, ajalu nla ko jalu eni a nwi, lojokan soso, gbogbo owo toni lotan porogodo, gbogbo iranse fokugan, gbogbo awon omo re, won ku la i ku kan soso, inu ileyi lowa laisan batude ba, lat’ori di atelese re kiki egbo ni, gbogbo awon ara ile re laanu, won ole pade, gbogbo ore laanu, won o le soro, fun odede ojo meta tete pa mo gbogbo won lenu, iyawo e tu soro ewe, I se niyen tu bere tu ni ma gbamoro ika, oni kobu Oluwa kobaale ku, kotaabuku Edumare kole d’iro saare, ibanuje nla wa d’ori agba kodo, gbogbo ile e wa kan gberigberi, eyen ni mose beebee lowolowo, ti mo nkepe Eledumare kankan f’eyin omo Olorun, f’eyin omo Igbala, lati oni lo, ajalu ibi koni jaluyin,

Oro ofo, Oro ekun, Oro ose, koni yale enikeni ninu yin, lagbara Oluwa Oba to wa laaye, towa lori ite, ire ire lomama je tiyin, igba t’awon ore Jobu t’otun ma soro nko, e se ni won gbe ipo sinu ina fun, won ni pele ore ohun to de ba e yi, oma jowa loju, isele to sele yii, obawaleru lopolopo, nitori na ore wa, iba jara kojewo, kojewo fun awa ore re, ese re iko ko, ese re ibaba, gbogbo ibi to n ti se, nitoripe b’ogiri oba lanu, alangba o n wonu e, ibadara ko jewo, kobaale ri anu gba, jewo fun wa ore wa, kajo beebee, katoro aanu, osa mo pe, alanu lolouwa, oba ako ma tika lehin, oya, baaba kohunko tajo bee Oluwa fun aanu, yii o dariji o, yii dabi duro, jewo ore wa, kole ra anu gba, Jobu gb’oro awon ore re, okan re gbogbe,

iya nla gbeni sole, kekeke bere si gori eni, awon toye ko tuninu, se ni won tu gun logbe okan, awon toye ko tuninu, ise ni won bere si da lagara, eni ani kofeniloju, ata lo lofis’enu, eni ani o kore wa lehin, e gu lolo fis’owo gidi, Edumare jowo gbawa lowo ajalu ibi, sugbon toba buru tan, asasi ku Eledumare, bi oba s’enikankan mo, ore kan si wa ti kii dani, Jesu loruko re, ohun lo duro tini lojo ogun ba le, ohun lowa pelu eyan, nigba ohun gbogbo ba d’ojuru, ti gbogbo ba de ileyi to fa gberigberi, benikeni kobasimo, enijan siwa sibesibe, ohun ni oba na, ogb’eja keru obonija, gbogbo eyin t’emo, gbogbo eyin te gbagbo, pe botihun kole to, Jesu si ma wa pelu yin sibe, e ke hallelujah s’olugbala

Jesu ye ni gba gbogbo
Jesu mi wa laaye
Jesu wa lat’oni lo o
Jesu mi wa laaye
Jesu pe wo o
Jesu mi wa laaye
O wa laaye o
Jesu mi wa laaye

Jobu dahun osi wipe, ohun toba hun yin ohun ni k’ema wi, Oro toba hun yin ohun ni k’ema so, sebi ohun tode ohun loni kamamo ohun, Oro to se ohun lo fa sabaabi, oni sugbon odamiloju saka, ohun wipe, oludanda mi be laaye, owa laaye titi aye, owa laye kole y’ipo pade, lojo ire, owa laye, lojo idamu, owa laye, nigba opo, owa laye, lojo aini owa laye, lojo ririje owa laye, lojo airije owa laye, nigba aisan owa laye, nigba ilera owa laye, lojo gbogbo, nigba gbogbo owa laye, niberi owa laye, lopin ohun gbogbo owa laye, atana, at’oni, at’ola owa laye saani, Edumare gbo, ohun ti Jobu wi, owo le lat’oke, o gbohun ti Jobu so, inu won dun, ori won wu, ni kia mosa, won paase irapada igba, won b’esu wi jo, ohun gbogbo tu wa tu di rere, aisan fo le, arun lo kia, ogun tan, idamubuse, wahala pehinda, ibanuje pari, ayo tu bere iwe, eni awi otun b’imo lemo, okunrin meji, obirin meta, to r’ewa lopolopo, owo tu yade, ……tukan lekan si, gbogbo ibukun oberise niwa ni ilopo ilopo, wa yi o, Oluwa f’emi gigun ke Jobu lola


Ogorin odun ni baba tu n wa fun si, oju wa t’ota, oju ti satani idi niyii eyin ara ti mo n fi paase, ti mo n so tele ni p’ese pe latoni lo, ekuyin a d’opin saani, ibanuje yin apada di ayo, gbogbo ikole yin loluwa ma da pada fun yin, e oni gb’oru aisan mo, oju ati ota yin, eyin a o r’iyin awon odi, eni reti pe k’iku e o gb’eyin gbogbo won, eni reti pe k’isofo, e yin loma bawon k’egun, eni bani k’oju oti yin, awon gan loju ma ti nigbehin, mo pa lase loruko oba titi aye, loruko okan Lana, okan na loni, okan na titi anipeku, pe lati oni lo, lat’inu ogo le o ma b’osi inu ogo, lat’ori oke le o ma losi oke t’oga, tobase teyin omo Olorun, tose teyin omo Igbala, awaju awaju le o ma lo, e oni d’iro eyin mo, ogo tun tun n bo, ogo tun tun feri de, lagbara Olorun oga ogo, e oni pa ninu re, teba gbamigbo pe bemotiwi, pe bee loma ri, e dide n le, eji ka jojo, k’eji kajoyo, eji ka yin baba logo nitoripe kini Jesu wa laaye e,


Oya titi aye o
Jesu mi wa laaye
Jesu ye ni gba gbogbo
Jesu mi wa laaye
Jesu lat’oni lo o
Jesu mi wa laaye
Jesu ye ni gba ku gba
Jesu mi wa laaye
Jesu ye lat’oni lo o
Jesu mi wa laaye


O n gbala ni gba ku gba
Jesu mi wa laaye
Jesu ye lat’oni lo
Jesu mi wa laaye
O n wosan ni gba ku gba
Jesu mi wa laaye
Jesu ye lat’oni lo o
Jesu mi wa laaye
B’oti n gbani bee lo n lani


Jesu mi wa laaye
Jesu ye lat’oni lo o
Jesu mi wa laaye
Hallelujah hallelujah
Jesu mi wa laaye
Hallelujah hallelujah
Jesu mi wa laaye
Jesu ye ni gba gbogbo
Jesu mi wa laaye
Jesu ye lat’oni lo o
Jesu mi wa laaye
Jesu ye ni gba ku gba
Jesu mi wa laaye
Jesu ye lat’oni lo o
Jesu mi wa laaye


O n gbala ni gba gbogbo
Jesu mi wa laaye
Jesu ye lat’oni lo o
Jesu ye ni gba gbogbo
Jesu mi wa laaye
Jesu ye lat’oni lo o
Jesu mi wa laaye
O nwosan ni gba gbogbo
Jesu mi wa laaye
Oya laye loni o
O n gbani ni gba gbogbo
Jesu mi wa laaye
Oye lat’oni lo o
Jesu mi wa laaye


O npesi ni gba gbogbo
Jesu mi wa laaye
Jesu ye lat’oni lo o
Jesu mi wa laaye
O npesi ni gba ku gba
Jesu mi wa
Jesu ye lat’oni lo o
B’oti n gbani bee lo n lani
Jesu mi wa laaye


Jesu ye lat’oni lo o
Jesu mi wa laaye
B’oti n gbani bee lo n lani
Jesu mi wa laaye
Jesu ye lat’oni lo o
Jesu mi wa laaye
O n lani ni gba ku gba
Jesu mi wa laaye


Jesu ye lat’oni lo o
Jesu ye ni gba gbogbo
Jesu ye lat’oni lo o
Jesu mi wa laaye
O nwosan ni gba gbogbo
Jesu mi wa laaye


O nwosan lat’oni lo o
Hallelujah hallelujah
Jesu mi wa laaye
Hallelujah hallelujah o
Jesu mi wa laaye

Kindly use watch the video via this link:

COMPILATIONS BY

MOSES DURODOLA AND FEMI AFUWAPE

DISCOVERY MEDIA CREW (DMC) © 2021

You may also like...

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Social Media Auto Publish Powered By : XYZScripts.com
error: Content is protected !!