EWI (POEM) RENDITION BY PASTOR E.A ADEBOYE DURING THE 70TH RCCG ANNUAL CONVENTION 2020 (VIDEO LINK INCLUDED)
Discovery Media Crew brings to you the lyrics of the poem (Ewi) rendered by Pastor E.A. Adeboye during RCCG 70th Annual Convention, August 11th, 2022. Theme: Perfect Jubilee.
Theme: Perfect Jubilee
Call: Ewa ba mi jo o
Resp: Odun mi tide igba mi ti ko /3ce
Call: Odun Jubilee
Resp : Odun mi tide igba mi ti ko
Call: Odun alayo o
Resp: Odun mi tide igba mi ti ko
Call : Ewa ba mi jo o
Resp : Odun mi tide igba mi ti ko
Call: Odun Jubilee
Resp : Odun mi tide igba mi ti ko
Call: Odun ayo
Resp: Odun mi tide igba mi ti ko
Call : Ewa ba mi jo o
Resp : Odun mi tide igba mi ti ko /2ce
Call: Odun Jubilee
Resp : Odun mi tide igba mi ti ko
Call: Odun ayo
Resp: Odun mi tide igba mi ti ko
Call : Halleluyah
Resp : Odun mi tide igba mi ti ko
Ki nto korin, mojuba eni ti oni orin
Ki nto ka ewi, mojuba oro ijinle
Mojuba eni to laiye
Mojuba eni ti oni orun
Oba to da wa si
Lati odun modun
Lati osu mo osu
Titi adorin odun
Ti ijo irapada ti bere
Mojuba eni ti o ni ohun gbogbo
Oba ibere
Oba opin
To ni ki imole owa
To si wa
Olorun Akindayomi
Oba to nwi
To ndi sise
To nsoro ti ki nye
Oba olojo
Ta nfi ojo fun
Oba oni gba
To nse eto igba de igba
Oba asiko
To nje k’asiko oko
Oba wele wele
Bi ebi ale
Oba wara wara bi ojo akoro
Owa lorun o nse okoso aiye
Owa loke ose eto isale ile
Alapa robi robi
Oba afi idi p ‘ote mole
Owo inu ile wa, ile po fofo
Orin irin ajo, lai kuro ni ipo re
Iba re o, Oba ibere
To saju ibere
O so ile osho d’ asan
O so ile aje d ‘ofo
Oba aja layi lo ada
Oba aja layi lo ibon
Opin gbogbo opin
Oba toti wa ki igba o to wa
Kabiesi olodumare
Bi mo ni kin ma ki yin
Ma so gbagbe Orin ti mo fe ko
Aki ki tan eleru niyi
Sebi ni atete ko se
Olorun da orun
Ohun aiye
Won da osan
Wosi da oru
Won da igba
Won se to akoko
Igba ojo
Igba erun
Igba ifuru gbin
Ati igba ikore
Igba iloyun
Igba ibimo
Igba ijo
Igba ayo
Ohun gbogbo ni igba wa fun
Igba la so
Igba lewu
Igba ni Jubilee
Odun idasile kuro ninu ide
Fun omode
Ati agbalagba
Igba na lo de wa yi
Fun emi ati eyin
Odun wa ti de
Igba wa ti ko
Aku orire
Aku ayo lopolopo
B’ Oluwa ti mbe
Ti edumare ni wa sibe
Igba ayo gbogbo wa yio bere loni gan
O ran mi leti
Igba ara birin kan
Wundia gidi
Arewa le niyan
O lowo, o lola
O wa la lafia
Okan re si bale
Afi igba ti esu da soro re e
Bi ere bi awada
O bere si ni se nkan osu re
Ere ni, awada ni
Loba di nkan odun
To ko ti ko da
Lo ko ti ko gbe
Lo nsun bi omi
Lo nro bi ojo
Ere ni, ewa ri
Obirin bere si nru
O bere si ngbe
Lo ro ba di oro onisegun
Akoko se ti, ofi ranse si ekeji
Ekeji seti, ofi ran se si iketa
Loro ba di oro atowo do wo
Loro ba di oro atagbagbe pataki
Titi owo fi tan
Bi oro buse lai ri iwosan
Lai ni alafia rara
Loba do ojo kan
Ni gba ti ojo ayo re de
Ta si kore to ko
Lo gbo pe Jesu ma nkoja
Ladugbo ohun
Jesu nrin bo, lai jina
Si bi ti oun wa
Emi kan wa so fun pe
Arabirin ojo re ti de
Igba re ti ko
Ti ide re yio ja
Lo ba pin nu lese ke se
Pe oun yio to Jesu wa
Pe ti owo oun ba le kan
Iseti aso Jesu
Ti owo oun ba le kan
Iseti aso oluwosan
Ara oun yio ya sa ni
Ide oun yio di awa ti
Igba ti ode odo Jesu
Ero lo bi omi
Opo ero lo yi Jesu ka
Sugbon ipinu re
Ole bi okuta
Ko bikita fun ero
Oro pata owo inu agbo
Oku gere owo inu ero
Bi o ti nbi awon kan sotun
Lo nbi awon miran si osi
Titi ti o fi de odo Oluwa oba
Oba oluwosan
Alagbada ina
Alawo Tele orun
Ni gege ti owo re kan eseti aso baba mi
Logan ni wara nse sa
Gongo so isele se
Ase jade lara Oluwa
Ose iyanu lara obirin yi
Isun eje re da wao
Isun eje dopin
L ‘esu ba te
L’ esu ba pofo
Lai pe lai jina Jesu wipe
Talo f ‘owo kan mi
Talo gbare ni jiji
Talo gba lati eyin
Talo gba idasile pataki
Peteru wipe Kabiesi oba a lagbara giga
Okika…. Oba igbala
Ero po to yi to yi yin ka
Ero lotun Ero losi
Etun bere pe Talo f’ owo kan yin
Jesu dahun oni Peteru
Ani enikan f ‘owo kan mi
I fowokan lasan ko leleyi
Ifowokan ara oto ni
Mo mo pe daju daju
Ase jade lara mi
Ase iwosan Ase iyanu
Ase itusile ninu ide
Lo birin yin ba no si waju
Owo le o teriba
Ojuba edumare
E emi ni, ani emi ni
Emi ni Eni ti amu lara da
Emi ni eniti a soro re dayo
Ide mi ti ja, mo ti gba itusile
Jesu dahun osi wipe
Dide arabirin, ma beru
Igbagbo re ti mu o lara da
Ma rin, ma nyan, ma lo ile re
Ninu ayo, ninu alafia, ninu ominira gidi
Okiki kan ariwo ayo ta
Oju tesu, pe su po fo
Lo birin na ba fo soke
Lo na fi Orin bo enu pe
Call: Ewa ba mi jo o
Resp: ayo mi ti de, igba mi ti ko
Call: Odun Jubilee
Resp : Odun mi tide igba mi ti ko
Call : Halleluyah
Resp : Odun mi tide igba mi ti ko
Kini idi t’ Olorun fi ran wa leti
Isele yi. Boya won fe ka ko eko
Bi meji tabi meta
Ikini, opo eniyan lo to Jesu wa
Enikan soso pere lo se orire
Enikan soso lo di eni aiye nbayo
Boya iwo leni na
To wa si agbo ajodun yi
Lati gba ire lowo Oluwa
Lati gba iwosan lowo edumare
To ba je iwo ni
Mo pase ki nto korin tan
Ki eni to dopin
O ma ri ire re gba sa ni
Eko keji, oni pe
Ipinu arabirin yi, ki ise kekere
Ko wa si ajodun wa wo ran
Ko wa si ajodun wa se awada
Omo oun to tori tire wa
Omo oun to fe gba lowo edumare
Iwo na wayi o
Ti o wa pelu ipinu to ga
Lodun yio ninu ajodun eleyi
E o ni lo lowo ofo
Ma ri iwosan temi gba
Ma kuro ninu ipo itoshi
Ma lalu yo
Ma di iya aburo
Lodun to nbo, temi tomo rere ni
Ma ri igbega lara, lokan, lemi
Ani se, mi ko ni pada bi mo ti se wa
Hun o pada pelu itusile Pata pata
To ba je iwoni, to ni iru ipinu be
B ‘Oluwa ti nbe
Ti edumare wa lori ite re
Mo pase lowo lowo bayi pe k’ ale o to le
Ko ‘run o to wo, oro re a dayo
O ma korin ti tun
Orin isegun, Orin ida sile
Orin ogo
Ani mo pase mo pase gidi gidi
Ki nto korin tan
Oro re a d’ ayo
Call: Ewa ba mi jo o
Resp: ayo mi ti de, igba mi ti ko
Call: Odun Jubilee
Resp : Odun mi tide igba mi ti ko
Call: Odun ayo
Resp : Odun mi tide igba mi ti ko
Call : Halleluyah
Resp : Odun mi tide igba mi ti ko
Eko keta wa yi o
Ti Oluwa ba se e lore
Ma se fi pamo
Bi edumare ba wo e san
Jeri e fun arayo gbo
Bi ogun aiye re ba se nse lowo lowo
Ma fi pamo, Jeri re fun gbogbo eniyan
Ai dupe, ai jeri, lo mu opolopo eniyan so ire Oluwa nu
Sugbon eni ba mo re
To njeri Oluwa, to npokikire
Ayo won a ma kale
Ayo won ki ndi baje
Oun ni mo se wipe
Ninu ajodun ti Odun yi
Gbogbo eyin omo Olorun
Gbogbo eyin omo igbala
Te o ma jeri Oluwa
Te o ma pe okiki re
Ide yin a ja pata po
Ominira atata lo ma je ti yin
Ile yin a bere si ni loju
Ona yin a bere si ni bayi
Gbogbo ogun at’odun modun
Gbogbo wahala at’ osu do su
Won a dopin sa ni
Lase edumare e o pada si Ile layo
Oju o ni ko yin ma
Osi oni ta yin mo
Ara yin a le
Ayo yin a posi
Lati oni lo, e o ma jo
E o ma yo, e o ma korin isegun
Ti e ba gbagbk, be lo ma ri
E dide nle ka jo jo,
Ka jo yin baba l’ ogo
Call: Ewa ba mi jo o
Resp: odun mi ti de, igba mi ti ko
Call: Odun Jubilee
Resp : Odun mi tide igba mi ti ko
Call: Odun ayo
Resp : Odun mi tide igba mi ti ko
Call: Ewa ba mi jo o
Resp: odun mi ti de, igba mi ti ko
Call : Halleluyah
Resp : Odun mi tide igba mi ti ko
Call: Ewa ba mi jo o
Resp: odun mi ti de, igba mi ti ko
Call: Odun ayo
Resp : Odun mi tide igba mi ti ko
Call: Ewa ba mi jo o
Resp: ayo mi ti de, igba mi ti ko
Call: Odun Jubilee
Resp : Odun mi tide igba mi ti ko
Call: Odun ayo
Resp : Odun mi tide igba mi ti ko
Call: Ewa ba mi jo o
Resp: ayo mi ti de, igba mi ti ko
Call: Odun Jubilee
Resp : Odun mi tide igba mi ti ko
Call: Odun ayo
Resp : Odun mi tide igba mi ti ko
Call : Halleluyah
Resp : Odun mi tide igba mi ti ko
TRANSCRIBED BY MOSES DURODOLA AND FEMI AFUWAPE
Recent Comments