EWI (POEM) RENDITION BY PASTOR E.A. ADEBOYE [AUDIO AND VIDEO INCLUDED]

67TH RCCG ANNUAL CONVENTION (SERVICE OF SONG)

THEME: “AND GOD SAID”

MINISTERING: PASTOR E.A. ADEBOYE

DATE: 8TH AUGUST, 2019

INTERLUDE TUNE (I shall not fail, I shall not fall, because of Jesus……..)

Listen to audio here

ORIN:

CHORUS:
Jesu Wipe yio dara fun gbogbo wa
Jesu ‘Oba
Awimayehun (Jesu) – 2ce

SOLO:
Jesu Wipe Agan yio bimo rere
Jesu ‘Oba
Awimayehun (Jesu)

… REPEAT CHORUS

Jesu Wipe Oku yio ji dide
Jesu ‘Oba
Awimayehun (Jesu)

… REPEAT CHORUS

Jesu Wipe Otosi yio di Oloro
Jesu ‘Oba
Awimayehun (Jesu)

… REPEAT CHORUS

Jesu Wipe yio dara fun gbogbo wa
Jesu ‘Oba
Awimayehun (Jesu)

… REPEAT CHORUS

EWI:
“NI àtetekọṣe oun ni Ọ̀rọ wà,
Ọ̀rọ wà pẹlu Ọlọrun, Ọlọrun si ni Ọ̀rọ na. Nipasẹ̀ rẹ̀ ni a da ohun gbogbo; laisi oro, ko si oun kankan ti a da.

Nitori idi eyi … ati omi, ati efufu lelele. Bi O ba pase fun Iji ki ji, iji adake roro, laipariwo kankan.
Bo pase fun Ina, ina a dawo jijo ni re duro.
Bi Won soro si Ilè, ile le gbe ota mi.
Ohun ti won ba so fun Okun, ohun ni Okun nse; Bi Won ni ko yago – a si di iyangbe Ile.
Ase Re l’òjò fi nyo,
Ase Re lo Orun fi nran.
Ti o ba ni ko Osupa o duro – Osupa a wa nibe titi.
Ohun ti Won ba ni ko wa – Ohun lo ma nwa.
Eyiti Won ba ni ko lo – yio lo dandan ni.
La Ase Re, Oke le shi idi. Bo ba se pase omi ajade ninu Apata.
Ohun ti Won ba sofun Eye – Ohun le eye nse.
Kiniun ko si laya kotapa se Ase Re ri.
Ati Ile, At’Oke, lo ngboran si Won lenu.
IBAA EDUMARE! Oba Asoro Maye!

Wayi ooo! Nitoripe Awon Lo da wa;
Eni ba si Dani, Lo le se Atunse eni.
Won le Wosan, Won le Tunda.
Ti o ba ni oun ti o ro, Tabi o di baje – Won le mu pada si IPO!
Eyi ti ko se tun se; Won APARO re! Pelu eya tun tun

Ti Won ba pase fun okunkun – Okunkun a pora!
Ti won ba pase fun Isé ati Iya – Gbogbo won adopin Pata po!
Oun ni mo se fe ki nkoko JUBA EDUMARE:

Oba Akodaa, Oba Aseda, Alewilese, Asoromaye, Bi won ba ti WI; be lo ma nri.
Oro Ijinle Agbenuomoeniyan fohun. Eleti Gb’aroye; Ako Matika lehin;
Won so Ile Iku daahoro; Won so odede Esu di oun awati; Ologo ni didan; Eleruniyin! Oba to Ngbani, Oba to Nlani.
Oun sise Ara – L’Orun at L’aye.

O f’Orun se Ite, O f’aye se ite Ese Re!
Oun J’Oba ninu Afefe,
Oun fi iji se sin gun
O mo Oni, O mo Ana, O mo Ola. Bo obade si ile, Ile akun fofo!
Oba Akomayago lona.

Oji loru, O tan ruru – Oba Atan ma bikita fun orun. Akikitan!
Oba t’ oun f’Oba je,
Agba Ijoye! Arin ti E loto oto; Ipinle, Opin. Oloruko bi eni layin! Kara kara Ara!
Jigi jigi bi ojo – KABIYESI; OBA ELEDUMARE!
JESU O…

ORIN Chorus:
Jesu Wipe yio dara fun gbogbo wa
Jesu ‘Oba
Awimayehun (Jesu)

EWI:
Oun loranmileti isele kan to sele lojo ojosi; lojo ojohun:
Okunrin Afoju kan gbo pe Oro to dara,
t’oun bawagbe –
ti a npe ni JESU. Oun koja lo ladugbo, O wa ni to si. L’afoju na ba figbe bonu; o ke tata: O lo gun to, o babe fun Aanu, Obebe fun Iyanu. Oke titi, ti JESU fi gbo igbe re! Ologun titi, ti JESU fi de ese duro. O ni ki won lo mu wa! K’ oun le mo – kilode to fi nke? Kilo nfe gan?

Lai pee, won mu wa si Iwaju JESU. BABA SORO, O si wipee: Arakurin, kini ohun t’ oun fe? Owo l’ oun fe ni tabi iparo ewu? Nitoripe mo ri o…… Se oun fe titun ni? Abi ti bawo?

Afoju na dahun, o si wipee – KABIYESI, ORO IJINLE: Bo se t’owo, mi o ba towo wa. Bo se ti ewu ewe; aso Ti eri ti mo bo sonu ni; Aso Ise, Aso Iya mi ni. (ti hun o si niwo mo LAILAI). Ti e ba le SAANU mi – ke so KIKI ORO KAN, k’ okukun le fi mi sile; k’ okukun le de opin ninu aye mi.

Aanu se JESU, O pase IMOLE, okunkun gbo Oro Agbara Re, o si FO LO! Oju Afoju LA, o riran kedere! Aso IYA, Aso ISE, Aso Egan, Aso Ibanuje di oun abo sonu (o do Ohun igbagbe).

ORO IJINLE SORO: Ase gun gidigidi! Atoro je ni, ko toro jeun mo. Eni Egan tele di, Gbajumo ni pese! Eni aye nte tele (ti won ko ka si eniyan): KIA lo di eni OTO! O d’ eni Iyi, O d’ eni Eye. IBAA EDUMARE! ORO IJINLE; Af’Oro lasan, SEGUN okunkun ni warawara! JESU ooo..

ORIN: Chorus
Jesu Wipe yio dara fun gbogbo wa
Jesu ‘Oba
Awimayehun (Jesu)

EWI:
Idi niyii, t’okan mi fi bale; to fi damiloju lai f’ota pe – Pe bi mo ba PASE loni, l’ Oruku JESU, ti mo pase lo ORUKO ORO NI – Bi mo ba ti wi, BEE lo ma ri. Ire ti mba su, fun eyin Omo OLORUN, ko ni YE – Koni T’ASE L’agbara Oluwa, L’agbara Edumare:

Ikini, Latoni lo – IMOLE a de sinu aye yin; Gbogbo Okunkun yio fi yin sile; Ogun Oso, Ogun Aje, yio di igbagbe ninu Ebi yin. Ogun Aini: Airi Na, Airi Lo, Airi Je, Airi Mu, yio di igbabe ninu aye yin – AMIN!!!!

Wayi o, LASE Akoda, Lase Aseda, Lase Asoromaye; Gbogbo oun to nfe Atunse, ninu aye yin: Lama tunse ki nto pari Orin. Eyi to nfe IPARO, JESU yio paro re. Ijikiji to le ma ja yin lowolowo, yio si WO Patapata! Gbogbo ogun OTA – Ota Ile, Ota Ode, Ti Amoniseni, ti Afi’ aimoniseni, Asenibanidaro – GBOGBO re ADOPIN latoni lo. Gbogbo Oke ISORO, bo tiwu ko GA to: yio di PETELE loni. To ba si ni Ota, to tele yin wa si ibi; won AYIPADA – Won adi ore yin. Eyi ti o ba ko (to fi ake kori) pe afi Orun nikan lo le je onla: Bo ba wa Lori ILE – Ile Agbemin. Bi o ti inu OMI wa – Omi Agbe won lo – AMIN!!!

Eyin t’aye ti Pa Ti; Eyin t’aye ti Gbagbe, Lehin Ajodun Yi – E o Di Oloruko Lahujo – AMIN!

JESU OOO

ORIN: Chorus
JESU Wipe, yio Dara fun gbogbo wa
JESU Oba, Awimayehun!

EWI:
LA AKOTAN; mo fe be yin l’ebe kan: Nitori ORO NI (ti ki yipada) to so pe o ma DARA FUN YIN; Oun na lo wi pee: E je Mimo, E yago f’ese; ko le ye yin kale; K’ola yin le sunwon. O ni ke Jere Okan ka Adura yin le gba. O ni ke koko wa Ijoba Ohun ati Ododo re, ko Ohun gbogbo le je afikun fun yin. T’eba gboran te esi se Ife Re, a je wipe Ayo yin sese bere ni.

Wayi o, ni PARI PARI re; Won LA Awon mbo wa. Won LA Awon npada bo. Won o si ni pe de. E je ka gbaradi. Ka mura sile ni tooto! Ka le ba lo LOJO OLOGO!

E yin Omo Igbala, e Ku oju lona fun Ipadabo JESU. E fo okan bale – Be ekun pe d’ale kan, Ayo mbo LOWURO! OJO AYO WA, o fere de tan. Sugbon ko to de – E DIDE NLE, e je ka Jo JO! Ka korin titun si OLORUN OBA; OBA ORO, JESUS OOO

ORIN: Chorus

JESU Wipe yio dara fun gbogbo wa
JESU Oba,
Awimayehun….

Jesu Wipe Oku yio ji dide
Jesu ‘Oba
Awimayehun (Jesu)

… REPEAT CHORUS

SOLO:
Jesu Wipe Agan yio bimo rere
Jesu ‘Oba
Awimayehun (Jesu)

… REPEAT CHORUS

Jesu Wipe Otosi yio di Oloro
Jesu ‘Oba
Awimayehun (Jesu)
oku yi o jinde…..
agan yio Bi mo rere….
Otosi yi o d’ oloro

Chorus
JESU Wipe yio dara fun gbogbo wa
JESU Oba,
Awimayehun….

Watch Video here

COMPILATION BY

MOSES DURODOLA, TITILAYOMI AJAYI, TOPE BABALOLA, OLUSOLA OLAYINKA AND FEMI AFUWAPE

© DISCOVERY MEDIA CREW (DMC) 2019

You may also like...

2 Responses

  1. Agim Chizoba says:

    Is there no way one can download this song? because I really love it even though I don’t understand all the words in the song.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Social Media Auto Publish Powered By : XYZScripts.com
error: Content is protected !!