EWI (POETRY): PASTOR E.A ADEBOYE, DAY 4 RCCG 68TH ANNUAL CONVENTION 2020

RCCG 68TH ANNUAL CONVENTION 2020 (VIRTUAL)

THEME: WONDERFUL

MINISTERING: PASTOR E.A ADEBOYE

DAY 4 EVENING SESSION TOPIC: EWI (POETRY)

DATE: 6TH AUGUST, 2020

You can listen to the audio here

You can also watch the video here:

Ara e bami yo Jesu ti so oromi dayo mo dupe /2ce
Call: eyin Jesu logo
Resp: Jesu ti so oro mi dayo mo dupe
Call: Jesu to gbamila
Resp
Call. Jesu to wo mi San
Resp.
Call. Otun da mi ni de
Resp.
Call. Otun wa bunkunmi
Resp
Call. Ara e ba mi yo
Resp.
Call. Eyin Jesu logo
Resp.
Call. Jesu to wo mi San
Resp.
Call. Jesu to gbamila
Resp.
Call. O da mi ni de
Resp.
Call. Otun wa bunkunmi
Call. Hallelujah
Resp.
Call. Hallelujah
Resp.
Call. Ah e ba mi yo
Resp.
Call. Ara e ba mi yo
Resp.
Call. Ara e ba mi yo o
Resp.

Bi iro ba nlo ni ogun odun
Bi ejina logbon osu
Ojo kan soso pere ti
Ni otito ma le won ba
Ojo kan soso, lai lagun
Otito agbon won re jina jina

Gbogbo omi to nbe lo kun
Gbogbo odo to wa lo sa
Won o le bori otito rara
Won o le te otito ri si isale
Bi gbogbo aiye gbina
Otito a si leke sa
Oro agba, bi ko tekun

You can also listen to the audio online: Ewi (Poetry) by Pastor E.A Adeboye replayed during RCCG 2020 Convention

A te ekoro
Oun oluwa ba ti wi
Dandan ni ko se ni gidi
Oro edumare ba fo
Ko ni se alaise laiye
Ise ti baba ba ran
Odi sese ni gidi
Se edumare lo soro
Pe ka so fun olododo
Pe ni didara oma dara fun won
Oba oke losoro
Oba oke lo pase
Pe alafia atata ni fun omo igbala

Oun ni mo se wipe
Gbogbo omo oluwa
Gbogbo omo igbala
Eku abo si odun ayo
Ire nla
Ire gidi
Loma kari yin gbogbo
Oro ayo sese yio be lodo yin ni pese

Orin ijo, Orin ope ni yio gbenu yin kan
Be ba ni, baba lo so fun mi be
Be si bere Pe tani beniwo
Ti mo fi mo Pe ojo ire yin ti de
Emi a si wipe baba mi oba oke
To tun ni isale
Oba a so eni di ana
Oba a so ana di ola

Alabalubu omi
Bi omode lo ri
Oke gogoro
Ti nja agbalagba laya
Agbon igbe omi
Alubulubu osan
Alagbalugbu obe
Ti nyo kan lenu
Agbaga omi a

Afisansi le
Baba mi ajigin
Arigini
Oginigini ojo
Arin ki ile odero
Owo inu ina kojo
Ojin so odo ko ri
Ogbamu gbamu oju orun ose gbamu

Arugbo ojo
Oba koni ibere
APA o ka araba
APA o ka rere
Owale ojo
Abale kile mi titi
Erin nla ko lube
Ajanaku ko riro fun okunrin
Ajanaku agba ajuru bambam

Ojo were wole
Orin girigiri WO oja
Erin lakatabu
Ekun abijawara
Baja ba nsinwi
Aja ama mo oju ina
Bi eniyan si were ewe
Asi papa yago fun ejo
Baba ina omo orara

Ole Jo igbe ki igbe o ma Jo
O si le sun apata ko di eru gidigidi
Baba mi oro ijinle
Oba a so orun di ero
Ko se mu, ko se pa
Kose binu si, kose de lewon
Erujeje oba a soke di petele

Bo oni komi oru
Gudugudu ama so
Bo ni ki iji osun
Asi gboran lesekese
Ojo t’afefe ti nfe
Afefe kan ko du gbegi ri
Ojo odo ti nsan bo
Odo kankan ko san GBA oke

Igi ti baba mi ba gbin
Eda kankan ko le fatu
Ona ti baba ba la sile
Eniyan kankan ko le dena na
Ohun a ma so eru do oba
Asi so iwefa di eni oye

Kabio osi si
Ta loto sope kini baba NSE
Baba mi, eja NLA to nfi inu ibi so ola
Kinihun Juda
Arin lo tan ni falala
Awodi agba
Agboju orun so ogo
Egbe ori omode
Oba asoro maye

Oti da eye agbe
To nfi aro se oge
To da aluko
To fi okun se ewa re
Be lo da lekeleke
Abaso funfun nini
Agba ijoye

Kose mu
Kose pa
Kose binusi
Kose de le won
Erujeje oba a soke di petele
Bonu ko omi oru
Gudugudu a ma so
Bo ki iji osun
Asi gboran lesekese

Ojo ti afefe ti nfe
Afefe kan ko tu gbegi ri
Ojo odo ti nsan bo
Odo kankan ko San gba oke
Igi ti baba mi ba gbin
Eda kan ko le fa tu
Ona ti baba ba la si le
Eniyan kan ko le dena na
Oun a ma so eru di oba
Asi so iwefa di eni oye
Kabi o osi si

Tan lo ntun sope ki ni baba nse
Baba mi
Eja nla to nfi inu IBU sola
Kiniu Juda
Arin lo tan ni falala
Awodi agba
Agboju orun sogo
Egbe ori omode
Oba asoro ma ye

Bo ti deye agbe
To nfi aro soge
To da aluko
To fi osun sewa re
Be lo da lekeleke
A baso funfun nini nini
Agba ijoye
Oba a sekan maku
o se owo omode
Owo omode ko to pepe
O se owo agbalagba

Agbalagba ko wo kegbere
O da inaki tan
Eyen a ma di igi korin
Agba ajanaku
A fun fere re lo Dan Dan
Se eni oluwa ba nda Lola
A won ni o ndi eni olola
Eni edumare ba bokun
A won ni anpe ni oloro eniyan

Eni oluwa ba gbega
Oun ni ondi eni giga
Afi aimo ki eni baba ko sile
Ma di edun arinle
Edi niyi
To fidami loju shaka
Pe eyin omo olorun
Eyin to ri igbala atata
Ni wiwa te wayi

Ire le ma mu lo
Oke isoro yin gbogbo
Adi le lai Ku kan
Edumare a be yin wo
Oba oluwa a gbe yin ga
Ileku ayo to ba si si fun yin
Titi aiye ko ni pade mo

Asu odara ko ni le ti lekun na
Eni ba si ni eni gberi
Oju won ni e o gberi
Eni ni e o ni goke agba
A won ni e o fi se ategun goke

Gbogbo oun to nko yin lominu
Gbogbo won le o wa fi dupe
Gbogbo oun to mi yin lokan
Gbogbo re a si di oro itan
Gbogbo igbe yin si oluwa
Gbogbo re lo ma gbo
Gbogbo ebe adura ewe

A si wa di eri atata
Lola oluwa giga
Lola edumare loke
Igbega yin ti bere Lati nsi ti lo
Oke oke le o ma lo

Chrs
Call: Ara e ba mi yo
Resp: Jesu ti soro mi dayo module…..

Oro de ori ko de ori
Ika ese ko kukan
Ete ti je leti
Ete ti te loda
Ati oju ati imu
Kiki egbo gidi ni
Owun papa si nrun
Bi oku akitan

O ti di eni aiye nsa fun
O di eni ore nyago fun
Ko je ara aiye nibi
Ko je ero orun gidi
Inu Igbo nla
Lo fi nse ile
Wayi o, aisan ara ni kan
Ko lo doju ko
Aisan okan pelu
Ndamure

Ko so owo lowo
Ko si ise latise
Ibanuje atata wa so ori adete kodo
Ko ri aya fe
De ibi ti o ro mo bi
Se bi aisan Ete
Loso di agan airotele
Kaka ko ni itesiwaju

Ojo jumo ni oun gbogbo nburu si
Iku ke ko si da ojo
Sare ko so igba kan na
Ti oun yio gbemi patapate
Oun gbogbo le koko koko
Bi oju eja eleja
Lojokan ose alaba pade Jesu
O pade baba mi peki

Nibi ti nwon ti NSE ore kiri
Adete wole wo
O josin fun baba mimo
O ba buru buru
Niwaju oba alagbara
O ni kabiesi
Oba to ni aiye to ni orun
Kabiesi oba ti oni ile to ni oke
Bo ba je ti ipa, eyin loni ipa

Bo ba je ti agbara
E o ni igba keji ewe
Eni eba pa, oun lo nku
Eni eba la, asi di alaye okan
Ti e ba fe e le so mi di mimo
Bi o ba wu yin
Oro Ete mi le di oro itan
Ti eba fe loku

Sugbon ti pe e o le se yen
Ka gba gbe re kia kia
Aseti kankan ko si lowo yin
Oba to ju oba aiye lo
Ti e ba sanu mi
Ti oro mi si di ayo
Aiye agbo, orun amo
Mafi ijo dupe
Mafi iyin dupe

Sugbon ni ba yi o
Mo ti sun
Moti kan ogiri
Eyi to Ku, owa lowo yin o
Eyin alewilese
Eyin alase lewi
Oba a sekan maku
Jesu wo titi

Anu se, pe eniyan lo jiya toyi
To di edun arinle lai Ku
Baba la enu re osi wipe mofe
Nse ni ko di mimo
Mofe ni se ni ko gba iwosan
Mofe pe ki oro e ko di Erin loni
Mofe ki ibanuje re ko di ayo
Ki ayipada o de
Ki oun gbogbo di rere

Baba mi na owo re
O fi kan Lori
Ni kia mosa
Gangan nla so
Isele Pataki se
Ara adete Mo kia
Ariwo bo fo
Ariwo nla ta ni gidi
Ariwo ayo lopo lopo
Mo si mo pe

Eni kan wa nibi ni nsiyi
Lowo lowo bi mo ti nkorin
Ariwo ope tire na yio ta
Ariwo ayo re na yio bere
ilekun ibanuje enu aiye re a si ti
gbogbo le o korin ayo lo le

chrs
call: baba mi yo o
resp: jesu ti soro mi dayo modupe
call:eyin Jesu logo
resp:
.
.
call: korin halleluyah
resp: Jesu ti so oro mi dayo mo dupe

Baba mi fi owo kan
O se oun tuntun
laiye lorun
nitoripe ewo ni
ki eni mimo fi owo kan adete
ewo ni ki eni mimo fi owo kan ailaimo pataki
eni ba dan wo, oun fun ra re asi di eni aimo

be ni ofin wi
be ni ofin so
sugbon baba mi lo se ofin
baba mi lo se igbekale re
ti ojo ire eniyan ba si de
baba mi le ni ki ofin ki o bila
ki anu le raye sise
ko ofin lo joko na

ko le raye dabira tire ni wara wara
iyen ni ose damiloju
pe ninu aiye yin
Oluwa yio se oun tuntun
ati oun ara ni pataki
bi aiye fe bi aiye ko
bi ofin fe bi ofin ko
loni yi gan, baba ma dabira sha ni
eyi anwi yi pe
iranlowo bere si nde
fun eni ti aiye ti nsa fun ri

fun eni ogba ti ko ni gba kan
ka to wi ka to fo
owo ti nya bi omi
gbogbo awon ebi ti oti pati ni gba kan
gbogbo wan lo nmu ebun wa
eyi to nfun lowo
eyi to nfun ni aso
ati bata asiko ewe
oun gbogbo wa nlo dede
oun gbogbo wa nlo dara dara

se bi aiyi ti da soro eniyan
lati odo Jesu wa
la nsope ona ko si
eni Oluwa ba dasi ti won
gere gere ni oun gbogbo ma nlo
lai fi ota pe
ibukun asi bere si ro bi ojo
eyin ara mi, ifowokan kan pere lati odo olidande
otito se oun gbogbo fun wa

osi da mi loju pe Oluwa oba yio fi owo kan yin lati oke wa
edumare yio fi owo kan yin
gbogbo oke gagara asi di nle le
Oluwa afi owo kan omo yin
wa si dagba ninu ogbon
a fi owo kan won loni
wa si dagba ninu imole re
baba mi a fi owo kan odo
eni ti o nwa oko, ari oko rere fe

eyi ti o nwa iyawo, a ri aya tire lai jina
gbogbo eni fe ka we
ona ti won na a la laipe
ire ire ni o ma je ti yin gbogbo
baba a fi owo kan abo yin
gbogbo a bi were
baba mi afi owo kan agan
gbogbo won a di iya ibeji
wan a fi owo kan arugbo

omi tuntun aru
eja tuntun a ba ibe yo
ta gba te iwe
a o jumo yo papo
be lo ma ri
be lo ma so
ori yin o ni ko adura
ti yin o ni soro se

chrs
call: ara e ba mi yo
resp: Jesu ti so oro mi dayo mo dupe

Sebi oluware atete fi owo kan baba
ma koja mi olugbala
ki i ma nse orin akunle ko
obirin oni isun eje ni
ko duro ki Jesu o fi owi kan oun
fun ra re lo lo fi owo kan baba
se bi owo ara eni ni afi ntun oro ara eni se

bi o ba se emi ni eyin ni
emi a fi owo kan baba loni
nipase igbagbo to le
igbagbo ti ko gba jo jo
pa pa leyi ti ijoba orun di afi agbara wo yi
ti alagbara nfi ipa gba ni gidi
ejowo efi owo kan Jesu ni ote yi

nipa adura to gbona
bi Bathemeu ti ke ke ke
ti Oluwa fi gbo gidi
bi Hannah se be be be
ti Oluwa so oro re di ayo
eyin na e ke tiyin
ke ba le royin ayo lai jina
te ba gbadura lai dake rara
te ke pe Oluwa ti osan ti oru
laipe lai jina, Jesu a dese duro

a ranse ayo si yin
Olu dande asi da yin ni de pata pata
bi o ba je ese lo fe dena ire yin ni ote yi
eba tete pinu gidi
lati jawo ninu ibi sise
ki efi aiye yin fun Jesu
ke fi ese sile e
ke sa to Jesu wa
ire gbogbo sa ni ti omo Olorun

lakotan eyin ara mi
e nfe ire abi e fe
e nfe ayo abi oti
oun rere gbogbo
owo Oluwa ni o ti nwa
ojo ayo atata odo edumare lo ti nro
boya boya kosi
oun ko ohun ti e ba nfe
baba a se won fun yin
oro efe ko baba mi ki se aseti

ti eba nfe ire
ti eti pinu ati jawo ninu ibi
ti e nfe ayo ti e ti fi ona esu sile
mo fi da yin loju
pe ki ale oni o te le
oba Oluwa a gbo ti yin gidi
a yanju oun e bebe re
ayo yin a kun

ibanuje yin a de opin
odun ayo yin a bere ni pese
sebi baba mi ni eledumare
akoda aiye aseda orun
ologbon lo ju
oni imo lodu
oba to nje oun gbogbo ninu oun gbogbo
airi aiku aisa aidibaje

aiyipopada aiyeraye nini aiyeraye
aiyeraye ninu awon orun
agba ijoye, ase ore ti re lodu lodu
kara kara ara
mona mona orun
oba to lo bele bele bi omi
ajinde iye ona otito
gbongbo idile Jesse

apata aiyeraye
irawo owuro
iyanu, oludamoran, ibere ti ko ni ibere
opin ti ko ni opin
ife ti ko ni abula
balogun laiye lorun
are gbogbo are

ijoye gbogbo ijoye
oba awon oba
ina oma orara
dugbe dugbe sanmo loke
idi nla ti ofi orun se ite
ese aramanda ti o fi aiye se itise re
owo aiyeraye

ti ngbeniga ju aiye
agba awodi
arin tire loto to
ba ani ko ro ti didun ifon
asi o ra de gun
bi mo ni kin ki yin tan
baba mi ale a le wa si bi

bi mo ni ki nyin yin terun
a o wa ni bi di ola
aki ikitan oba eleru niyin
eyin ara mi, eyin omo igbala
e o jo abi e o jo
e o korin abi e o korin
Eje ka Jo Jo
Ka korin tuntun si Oluwa

Chrs:
Call: ara ebamiyo
Resp: Jesu ti so oro mi dayo modupe
……..

Thank you so much for staying all through to read.

Watch the video here

To read other Messages on the Coverage of DMC MediaCrew so far this Year and beyond; kindly visit our Website: http://discoverymediacrew.com.

Follow us on Twitter: https://twitter.com/discoverymediac

Send a Friend Request on Facebook to DMC MediaCrew.

Like our FB Page: Discovery Media

Join us on WhatsApp:
https://chat.whatsapp.com/D20e9cqYX1LKKPm9n93K4h

Join us on Telegram: https://t.me/joinchat/NzzPckuGazKYFxZZFkt9fg

Follow Us on Instagram: Discoverymediacrew

Watch and Follow Us on YouTube: Discovery Media Crew

For Enquiries, email Us on: info@discoverymediacrew.com

And I can assure you that you will be glad you did as it will avail you first hand access to comprehensive reports on the various Messages of Pastor E.A Adeboye and other Men of God!

It is outrightly wrong and a sin we frowned at it for anyone to consciously remove the original source of the work that does not emanate for him or her!

Discovery Media Crew … Reaching out to the World through the Power of the Gospel!!!

COMPILATIONS BY:

MOSES DURODOLA, TITILAYOMI AJAYI, FEMI AFUWAPE AND TOPE BABALOLA

© DISCOVERY MEDIA CREW (DMC) 2020

You may also like...

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Social Media Auto Publish Powered By : XYZScripts.com
error: Content is protected !!